Luke 19:41-44

41 aNígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43 bNítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 44 cWọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”

Copyright information for YorBMYO